Matiu 17:22-23
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
22 (A)Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. 23 Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi.
Read full chapter
Matiu 20:17-19
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Jesu tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀
17 (A)Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, 18 “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. 19 Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
Read full chapter
Luku 17:25
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
25 (A)Ṣùgbọ́n kò lè ṣàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.
Read full chapter
Matiu 17:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.”
Read full chapter
Matiu 26:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.