Luku 9:27
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
27 (A)“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”
Read full chapter
Daniẹli 7:13-14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 (A)“Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí Ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀. 14 (B)A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.