Add parallel Print Page Options

(A)Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
    mú kí etí wọn kí ó wúwo,
    kí o sì dìwọ́n ní ojú.
Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
    kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
    kí wọn kí ó má ba yípadà
    kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

Read full chapter

10 (A)Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bí i pé, “Èéṣe tí ìwọ ń fi òwe bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀?”

11 Ó sì da wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a ti fi fún láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wọn. 12 Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà. 13 Ìdí nìyìí tí mo fi ń fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀:

“Ní ti rí rí, wọn kò rí;
    ní ti gbígbọ́ wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sì yé wọn.

14 (B)Sí ara wọn ni a ti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Isaiah ṣẹ:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọ́n kì yóò sì yé yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.
15 Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́
    etí wọn sì wúwo láti gbọ́
    ojú wọn ni wọ́n sì dì
nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí
    kí wọ́n má ba à fi etí wọn gbọ́
    kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òye,
kí wọn má ba à yípadà, kí èmi ba à le mú wọn láradá.’

Read full chapter

17 (A)Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. 18 Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?

Read full chapter