Add parallel Print Page Options

15 “Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 16 (A)Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 17 Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí. 18 Ìwọ ó sì ṣe ogún (20) pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, 19 Ìwọ ó sì ṣe ogójì (40) ìhà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìsàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 20 Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó síbẹ̀ 21 àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 22 kí ìwọ kí ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 23 kí o sì ṣe pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn. 24 Ní igun méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bákan náà. 25 Wọn ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

26 “Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 27 Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà. 28 Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà. 29 Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

Read full chapter