Add parallel Print Page Options

Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

Read full chapter

31 gẹ́gẹ́ bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì kọ́ ọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú Ìwé Òfin Mose, pẹpẹ odindi òkúta, èyí tí ẹnìkan kò fi ohun èlò irin kàn rí. Wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà ní orí rẹ̀ sí Olúwa.

Read full chapter